Igbeyawo ode oni

YORUBA LANGUAGE
JSS1
OSE KERIN
IGBEYAWO ODE ONI

Igbewyawo ode oni pin si orisi Meta.
A. Igbeyawo kootu
B. Igbeyawo soosi
C. Igbeyawo mosalasi
A. Igbeyawo Kootu
Ilana Igbeyawo kootu

  1. Iforuko sile:- Awon ti won fe fera ni yoo lo fi to akowe kootu leti,ti won yoo fi oruko sile pelu foto pelebe meji.
  2. Ikede:- Akowe kootu yoo fi iwe ikede ati foto won sita fun ojo mokanlelogun lati fi kede.
  3. Igbeyawo ninu iyara kootu:- Oko yow a eleri kan, Iyawo naa yoo wa eleri kan. Akowe kootu yoo fun won ni oro iyanju, wa se ibura pelu bibeli, kurani tabi ogun gege bi ami esin won. Oko yoo fi oruka boo mo ika keerin owo osi iyawo, Iyawo naa yoo se be fun Oko re bi ami Ife.
    B. Igbeyawo Soosi
    Ilana Igbeyawo Soosi
  4. Ifito Alufa leeti:- Okunrin ni yoo fi to Alufa leti, bi o ba ri eni ti o wun ninu Ijo.
  5. Igbawe Ase Ijoba:- Okunrin ati Obinrin ti won fe se Igbeyawo gbodo gba iwe Ase lati ojo Ijoba pe won le ferawon,
  6. Ikede:- won a se ifilo ni akoko Ijosin nigba meta, erongba won lati di tokotaya ati pe bi enikan ba ni idi ti Ijo ko fi gbodo so won po, ki o fi to Ijo leti.
  7. Idanileko:- Alufa yoo ya ojo tabi akoko kan soto laarin ose lati fi se idanileko fun tokotaya.
  8. Igbeyawo:- Gbogbo ebi ati ore ni won yoo pese sinu soosi ni ojo ayeye igbeyawo, awon tokotaya yoo jeje lati je okan titi aye.
    C. Igbeyawo Mosalasi
    Ilana Igbeyawo Mosalasi
  9. Igbayonda:- Aafaa yoo bere bi baba iyawo ba yonda omo re fun oko re, yoo bi omo okunrin bi o ba je ooto nip e o fe fe arabinrin naa. Bi idahun ba je beeni, Aafaa yoo tesiwaju.
  10. Owo ife:- Aafa yoo pase ki oko gbe owo ife ti won ti gbe sinu awon olomori wa.
  11. Adura:- Aafaa ati awon amugbalegbe re yoo kewu, gbadura fun idile meeji, beeni won yoo gba owo adura.
  12. Oro iyanju:- Aafaa tabi agba janmon ni yoo gba oko ati iyawo ni imonran.
  13. Idana:- won maa n ko eru ana bi ogede wewe, osan, opon-oyinbo ati bebelo wa sibe. Won yoo di kurani, age ikirun.
  14. Adura Ikadi:- Leyin yigi siso, won yoo fun tokotaya ni Oruka. Leyin adura iyawo yoo tele oko re sibi ti won yoo ti setoju awon alejo.