YORUBA LANGUAGE
JSS1
OSE KEFA
ISORI LITIRESO APILEKO
Litireso Apileko ni Isori ewi, iwe itan aroso tabi iwe onitan ti onkowe ko sita fun kika. Litireso Apileko pin si isori Meta:
A. Ewi
B. Itan Aroso
C. Ere Onitan
A. Ewi:- Ewi Apileko ni ero ijinle lori ohunkohun ti o ba ti inu eni wa, ti o jenilokan ti o si munilara, ti a ko sile ni ede ti o dun ju bi a ti se so oro lasan lo. Ewi apileko je ewi ode oni ti awon akewi fin toka si awon ohun to ni lawujo.
Abuda Ewi apileko
- Ila seku-seku ni a n ko ewi
- Ila ewi kookan le kun ju ara won lo
- Ede ewi maa n jinle. Akewi le lo oro kekere lati fi so ohun repete
- Koko oro inu ewi maa n han kedere
B. Itan Aroso:- ni awon iwe itan ti onkowe fi ogbon atinuda ko fun kika lati fi koni logbon tabi fun idanilara ya.
Abuda Itan Aroso - o maa n wa ni isori tabi ori
- Ede ita aroso maa n lo taara, o maa n dun ka
- O maa n ni olu eda itan ati awon eda itan miran
- Ahunpo orisi itan maa n waye
- Isele inu iwe itan kin saba je otito sugbon o maa n jo isele oju aye.
C. Ere Onitan:- Iwe ere onitan je iwe to onkowe fi ogbon atinuda ko ni liana itakuroso laarin awon eniyan fun kika, lati fi koni logbon tabi fi danilaraya. Iwe ere onitan maa n ni akole, be ni a le fi se ere oritage.
Abuda iwe ere onitan - Oruko akopa maa n wa ni akoole
- Itakuroso laarin awon akopa yoo siwaju koloonu(;)
- Bi onkowe ba fe sapejuwe nkan, inu akamo[] ni yoo koo si ni ara oto
- Won maa n ni olu eda itan ati awon eda itan miran
- Won maa n ko ni idan tabi iran:apeere idan kin-in-ni
- O se fi seere ni oritage