ATUNYEWO AROKO LAYE ATIJO
Aroko je ona ibanisoro lai lo Oro enu. Aroko je ona ti awon baba-nla wa fi ba Ara won soro asiri lai fi enu so.
Ami ni won fi n ranse so eni ti ko si ni itosi, ti eni naa yoo si ti mo itumo ohun ti won fi ami naa so.
ORISIRISI AROKO AYE ATIJO
1.AALE
Aale ni ami ti a fi maa n le eru tabi eso. A le so mo ara nnkan lati kilo fun awon ole lati ma se mu nnkan naa.
Apeere ale lile:
1.Ikarahun igbin ti a fi le eru: Eni naa yoo ya abuke
Akisa aso : iponju nla yoo ba eni naa
Magun ni Ara obinrin : Okunrin to ba sun mo obinrin naa yoo ku.
OHUN TI A FI N PAALE
Ikarahun igbin, akisa aso,.
suku agbado,ewe gbigbe,.
Aso pupa, okuta magun abbl.
OHUN TI A LE PAALE LE
Igi osan, oko agbalumo, ile oko, oko agbado, ewebe, oju ona, ara obinrin
Tesoo: ni aale ti a fi si Ara omo ile iwe tabi omo ekose ki o le raaye kawe tabi kose re ja.