Ami iparoko laye atijo ati itumo won

AMI IPAROKO NI AYE ATIJO ATI ITUMO WON

AMI ITUMO
1.Owo eyo———- eni naa ti di eni itanu
2.Ikarahun igbin————-ife Nini, okan re n fa mi.
3.Awo ehoro———— sa jinna rere, Ewu wa nitosi.
4.Awe obi———– Oro ti yanju
5.Sigidi———— Eni naa n sere ete tabi o fe te
6.Omo ayo———-Ala pe eni naa yoo di olomo laye
7.Edun ara( laarin awon oni sango)———–Ki eni naa ma binu mo.
8.Suku agbado——–Ihoho ni eni naa yoo ku si.
9.Iyepe inu ewe———– So otito fun mi bi Oro naa se je.
10.Eja ati akan——- aburu ati ire
Eja tumo si pe: Oro ko bo si
Akan tumo si pe :Oro bo si

  1. Iye Ayekooto——– Soro lati so otito
  2. Esuru——- Oro naa ko gbodo su o
  3. Igbale/Owo——– Jade ni ile mi tabi ki eni naa le eni ti o mu aroko naa wa Jade ni ile re.
  4. Irosun——– Wa sile kiakia, iyawo re ti bimo tabi je ki ija aarin wa pari patapata
  5. Awo oju ilu————-Oro ti kuro ni ohun asiri, gbogbo eniyan lo ti mo.