Atunyewo Aroko pipa laye atijo

             ATUNYEWO AROKO LAYE ATIJO

Aroko je ona ibanisoro lai lo Oro enu. Aroko je ona ti awon baba-nla wa fi ba Ara won soro asiri lai fi enu so.
Ami ni won fi n ranse so eni ti ko si ni itosi, ti eni naa yoo si ti mo itumo ohun ti won fi ami naa so.
ORISIRISI AROKO AYE ATIJO
1.AALE
Aale ni ami ti a fi maa n le eru tabi eso. A le so mo ara nnkan lati kilo fun awon ole lati ma se mu nnkan naa.
Apeere ale lile:
1.Ikarahun igbin ti a fi le eru: Eni naa yoo ya abuke
Akisa aso : iponju nla yoo ba eni naa
Magun ni Ara obinrin : Okunrin to ba sun mo obinrin naa yoo ku.
OHUN TI A FI N PAALE
Ikarahun igbin, akisa aso,.
suku agbado,ewe gbigbe,.
Aso pupa, okuta magun abbl.
OHUN TI A LE PAALE LE
Igi osan, oko agbalumo, ile oko, oko agbado, ewebe, oju ona, ara obinrin
Tesoo: ni aale ti a fi si Ara omo ile iwe tabi omo ekose ki o le raaye kawe tabi kose re ja.

 1. AAGA
  Eyi ni ami ti a ta mo ara igi meji ti a ri mole lati fi kilo fun eniyan lati sa fun ewu.
  Apeere aaga tita
  Si ori aatan : Ki eniyan ma da idoti sibe.
  Si ori ilr tabi oko : Enikeni ko gbodo gba ibe koja.
  OHUN ELO AAGA TITA
  Mariwo ope, aso pupa,.
  Eni tabi okun agba ti a ta mo igi
  IBI TI A LE TA AAGA SI
  Ojubo orisa, ori akitan, ori ile tabi ile to ija wa lori re.
 2. ITUFU
  Itufu ni awon nnkan to let mi ina wa, to a gbe si eyinkule eniyan lati kilo fun iru eni bee pe ki o jawo kuro ninu iwa ika kan. Bi bee ko, won n bo wa jo ile re.
  Awon ohun itufu
  Isana, oguso, epo oyinbo(kerosene), iha, pentiro( petrol), gaasi.
 3. ASEWELEWE
  Jija ewe tutu sile ni ikorita . Bi ami ni lati fi so fun awon tiwon dijo nlo si ibi kan pe awon to koja so iwaju.