1 of 2

Atunyewo Eko Ile

Atunyewo Eko Ile

Eko ile ni awon eko ti awon obi gbodo ko awon omo won ni ile. Iru eko you ma bere lati kekere. Eko ile se pataki ninu igbesi aye eda, bakan naa, o je koseemani. Eyi lo faa ti won fi maan sope “Ile la ti n ko eso rode”. Omo ti won ko to si gba to si n mu eko naa lo ni awon Yoruba n pe ni “Omoluabi”.

Abuda Omoluabi

 1. Ibowo fun agba: Ojuse awon obi ni lati ko awon omo won bi won see bu owo fun agba. Awon Yoruba maa n so pe “ omode to ba mo owo we yoo ba agba jeun”. Eyi ni pe omo bee yoo ri awon anfaani gba lati owo awon agbalagba. Omo ti ko ba bowo fun awon agba ko le ri ohunkohun gba lati owo awon agba. Omobinrin gbodo kunle nigba ti o ba n ki agbalagba, bakan omokunrin gbodo dobale lati ki awon agbalagba.
 2. Nini iwa rere ati suuru:Iwa rere pelu suuru se pataki ninu igbe aye omo eda. Bi eniyan ba yan ori rere sugbon ti ko ni iwa rere, awon Yoruba gba pe aye ati orun iru eni bee ko le dara rara.
 3. Iforiti: Eyi naa se koko ninu aye eda, bi idojuko tabi ipenija ba de ba eda. A gbodo ko omode bi won se n fori tii, ti won ko ni fi ni si ese gbe tabi se ipinu to le ko wahala ba won. Eyi lo faa ti won fi n so pe “ Iforiti lo ni ohun gbogbo”.
 4. Otito ati Oro Rere siso: Otito siso je okan pataki ninu awon ohun ti obi gbodo ko omo lati kekere. O ye ki awon obi ko omo lati kekere pe iro pipa ko dara. Bakan naa won gbodo ko omo lati maa n ni ohun rere lenu nitori awon Yoruba maa n so pe “ Oro rere nii yo obi ni apo, oro buburu nii yo ofa lapo”. Omode kii soro buburu lenu.
 5. Igboran: Igboran se pataki fun awon omode , igbonran ni kii je ki omode se asise. Awon obi gbodo ko omo pe omo to ba gba eko ile kii warunki nigba ti won ba n ba iru omo bee wi. Omo to ba mu imoran agba lo ni a n pe ni ologbon omo.
 6. Ifarada: A gbodo yera fun ohun to je mo ikanra ati  iwa igberagalati maa ni irepo pelu awon eniyan.
 7. Imowa fun oniwa: A gbodo mo pe iwa eniyan meji ko le dogba. Lati wa ni irepo, a gbodo mo iwa fun oniwa.
 8. Suuru Nini ni asiko wahala: Awon agba maa n so pe “Onisuuru nii fun wara kinniun”. Ti a ba ni suuru, igbepo wa ni awujo koni soro rara.
 9. Yiyan ore to dara: Eyi se pataki lati ko awon omode ki won ma baa ko egbe buburu ti o le ko won so wahala.
 10. Nini Iberu Olorun: Eni ti o ba ni iberu Olorun kii huwa buburu si omolakeji.

ISE SISE:

 1.  So ona marun-un ti a le gba lati huwa Omoluabi.
  1. Daruko iwa Omoluabi marun-un to le je ki a wa ni igbepo alaafia ni awujo.