1 of 2

Atunyẹwo Iṣẹ abinibi

     Atunyẹwo Iṣẹ abinibi

          “Iṣẹ ni oogun iṣẹ

          Ẹni iṣẹ n ṣẹ ko ma bọ ọṣun

          Oran ko kan ti oṣun

          Ibaa bọ oriṣa

          Ibaa bọ ọbatala

          Odi ọjọ to ba ṣiṣẹ aje ko to jẹun”

Arofọ oke yii se afihan bi iṣẹ ṣe je pataki laarin awon Yoruba . Awon Yoruba gbagbo pe iṣẹ ni oogun iṣẹ  . Idi ni yi ti o fi jẹ pe kaakiri ile Yoruba , iṣẹ ni wọn maa n fi owurọ ṣe . Iran Yoruba lodi si imẹlẹ  ṣiṣe wọn gbagbọ wi pe  “Ọwọ ẹni kii tan nii je”. Bi oni kaluku ba ti ji, idi iṣẹ wọn ni wọn n gba lọ . Idi niyi ti wọn maa n powe pe “Idi iṣẹ ẹni laa ti mọ ni lọlẹ ” .

Pataki / Iwulo iṣẹ Abinibi

  1. Iṣẹ abinibi jẹ iṣẹ ti a le fi le ọmọ gẹgẹ bi iṣẹ aṣela tabi ọna ọla .
  2. O ma n dena airiṣẹṣẹ laarin ebi  .Ko fi aye sile fun arinkiri awọn ọdọ . Awọn Yoruba maa n sọ pe ” Ọwọ to ba dilẹ ni eṣu maa n ya lo” .
  3. Ko si pe a n dajọ akoko ti ọmọ yoo lo lẹnu ẹkọṣẹ nitori pe lati kekere ni yoo ti maa foju  si iru iṣẹ bẹẹ titi ti yoo fi dagba ti ọkan rẹ yoo si ti balẹ si iṣẹ naa ni ṣiṣe

Orisirisi Iṣẹ Abinibi

  1. IṢẸ AGBẸ: Iṣẹ agbẹ ni iṣẹ ti o gbajumọ julọ ninu iṣẹ ti wọn n se ni ilẹ Yoruba . Awon agbẹ ni wọn maa n gbin ounjẹ ti wọn si n pese ounjẹ fun awọn eniyan  . Ounjẹ ti a n je lo n fun ara wa lokun ati agbara  lati ṣiṣẹ  . Idi niyi ti wọn fi sọpe ” Ọna ọfun ọna ọrun”  . Bẹẹ bi ebi ba ti kuro ninu iṣẹ iṣẹ buṣe .

Pataki ati Iwulo Iṣẹ Agbẹ

  1. Ipese ounjẹ : Awọn agbẹ ni wọn maa n pese ounjẹ fun awọn maa n pese ounjẹ fun awọn ara ilu  . Awon agbẹ lo n gbin iṣu  , paki , agbado ati awọn ewebẹ lorisirisi . Bi awọn agbẹ ba kọ ti wọn ko dako mọ afaimọ ki ebi ma wo ilu .
  2. Ipese ohun- elo fun awọn ile-ise : Awọn ohun mimu bii Bọnfita ati Milo , koko tibagbe kore ni wọn  fi n se wọn . Bi agbẹ ko ba gbin igi rọba  , ile-iṣe taya ko le ri oje rọba ti wọn fi n  ṣe taya  .Ireke ti awọn agbẹ n gbin ni wọn mfi n ṣe suga , bakan naa ni wọn  lo igi lati fi ṣe  pepa ti wọn fi n se iwe ati bẹẹ bẹẹ lọ .
  3. Ipese  ohun amuṣọrọ Aje : Awọn ohun agbin bii koko , epa , epo-pupa , rọba ati bẹẹ bẹẹ lọ jẹ ara ohun ti a ri fi ṣọwọ si oke-okun . Owo goboi si n wọle si apo yọba ati awọn agbẹ aladanla .
  4. Ipese iṣẹ : Iṣẹ agbẹ ṣiṣẹ mu airiṣẹṣe dinku lawujo .