1 of 2

Atunyewo silebu

                                       ÀTÚNYẸWÒ SILEBU

Silebu ni ege ọrọ tí o kéré jùlọ ti a lè pè jáde ní ẹnu ní orí iṣemii kan ṣoṣo.
Àbùdá Silebu
(i) Silebu lè jẹ iro fawẹli kan tàbí iro kọnsonanti àti fawẹli.
Àpẹẹrẹ: ì – yá
bà – bá
kọ – bọ̀
ẹ – gbọn
(ii) Iye ibí tí ohùn bá tí jẹ yọ nínú ọrọ kab ní yóò fi iye silebu tí ọrọ naa ní hàn. Bí àpẹẹrẹ:
Ìfẹ́ – Ibi meji ni ohùn tí jẹ yọ. ( Silebu méjì)
Omuti. – Ibi mẹta ni ohùn tí jẹ yọ (Silebu mẹta)
Ìkádìí – Ibi mẹrin ni ohùn tí jẹ yọ (Silebu mẹrin)
ÌHUN SÍLÈBÙ
Apá méjì ni silebu pin si . Awọn ní:
(i) Odo Sílébù : odo sílébù ni ìpín ti a máa ń gbọ ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori rẹ ni ami ohùn ń wa. Iro fawẹli tàbí kọnsonanti aranmu aṣesilebu ‘n’ ni wọn lè jẹ odo silebu . Odo silebu ni a fala sì nídìí wọnyi:
ì – wà
ì – gbà – là
ò – ro – n – bo
(ii) Àpàlà Silebu: Awọn iro ti a kì í gbọ ketekete ti a ba pè ọrọ síta . Kọnsonanti inú silebu ni o máa n duro bíi apaala silebu . Apààlà silebu ni a fala sí nìdii wọnyi:
ì – wà
ọ – sàn
dù – n – dù

ẸYÀ ÌHUN SILEBU
(i) Silebu Onifawẹli Kan (F) : Eyi le jẹ ẹyọ fawẹli kàn ṣoṣo:
Àpẹẹrẹ iro fawẹli bẹẹ ni a fala sí nídìí wọnyi:
A ti lọ.
Mo ri ọ.
Mo kà á.
Gbogbo iro fawẹli wọnyi le da dúró bíi silebu:
a, e, ẹ, ì, o, ọ,u.
(ii) Silebu Alahunpọ Kọnsonanti ati Fawẹli (KF). Àpẹẹrẹ irú silebu bẹẹ ni wọnyi :
Wá, bá, bọ, bẹ, rí , ra, mọ, kọ
Gbọn , rán, tán, rìn, kun , wọn
(iii) Kọnsonanti aranmupe asesilebu (N). Àpẹẹrẹ irú silebu bẹẹ níyì:
nlọ
o – ró -n -bó
i – sá – ń – sá