AWON ASAYON IWE LITIRESO

SS1, 3rd term ( note) 3rd week.
AGBEYEWO AWON ASAYAN IWE LITIRESO: ( NITORI OWO– Akinwunmi lsola )
(I) Onkowe safihan orisii idile meji otooto, idile Adio oko Abeni ati idile Oloye Oladejo oko Adijatu.
(ii) Oruko omo kansoso ti Adio bi Ni Oyeladun, dida to won da Adio duro ni ibi ise re lo sokunfa bi Abeni iyawo re se mu omo re Oyeladun lo si odo Alhaja Adijatu fun omo odo sise, ki o le ri owo lati tesiwaju ninu eko re.
(iii) Eyi mu ki Anfaani o si sile fun Oloye Oladejo lati maa se wolewode pelu Abeni, iyawo Adio.
(iv) Opo igba ni Abeni maa n gba aso ni awin lowo Alhaja Adijatu fun tita, ti yoo si San owo oja naa fun ni gere ti o ba ti ta a. Awon oja peepeepee ni Abeni n ta, ti ko si to gbo bukata ile.
(v) Baba Adio ka Oladejo mo ile omo re pelu Abeni iyawo Adio, Oladejo gbiyanju lati pa Oro nsa mole nipa fifun baba Adio ni owo ti onitoun si ko owo naa.
(vi) Okunfa didaduro ti Oladejo fi da Adio duro lenu ise niyi.Asiri Adio nitire ko sai tu nigba ti Baba Adio parada di egungun ti o si lo si ile Oladejo ti o n so fun in pe ki o ma a jewo fun Adijatu iyawo Adio ti o n ba ni ajosepo. Ibe naa ni o ti han si Oladejo pe Adio paapaa nba iyawo Oun ni ajosepo.
(vii) Omo odo Oladejo ni Bayo, Adu je ore Oladejo, dereba Oladejo ni Alabi; ise isowo ni ise Oladejo, ise dereba oko lo gba Adio fun.
( viii) Ara awon esun ti o fi kan Adio ni pe, o maa n ji oja ko wasile, O si tun maa n ba iyawo Oun ra komu ati pata wa sile.
EKO lNU lTAN
( I) ki a maa ni suuru lakoko isoro.
( ii) ojukokoro ko dara
( iii) itelorun se Pataki
(iv) iwa arekereke/ Ile dida lewu lopolopo.
( v) ki a jinna si iwa agbere.
( vi) ki a ma se so ireti nu nipa ojo ola.
(vii) igbagbo ati igbekele ninu Olorun le mu wa bori awon isoro wa.
(viii) isokan ati ifowosowopo laaarin oko ati aya lo le mu ki idile se aseyori.