YORUBA LANGUAGE
JSS1
OSE KARUN
IKORA – ENI NI IJANU SAJU IGBEYAWO (IBALE)
- Asa Ibale (Biba obinrin nile) se Pataki pupo ninu Asa Igbeyawo Ibile yoruba.
- Ibale ni Aami ti a fi n mo Omobinrin ti o ko ara re ni ijanu nipa pipa ara re mo di ojo igbeyawo ki o to mo okunrin tabi ni ibasepo pelu okunrin.
- Ale ojo Igbeyawo leyin poposinsin, ti awon alabase ti lo sun ni oko yoo wole to iyawo re lo ni yara lati ba ni asepo fun igba akoko.
- bi iyawo ko ba ti mo okunrin ri, abe re yoo ha, bi oko ba wa fi ipa wole ti eje si jade ni oju ara obinrin, iyen nip e oko ba iyawo nile tabi pe oko ti ja ibale iyawo re.
- Eje ti o jade ni oju ara iyawo yi ni oko yoo fi aso tabi owu funfun nuu bi ami pe iyawo da pe.
- Ti oko ba ba iyawo nile, ekunrere agbe emu tabi odidi igbon isana pelu aso tabi owu ti won fi eje ibale yi ni won yoo fi ranse si idile iyawo pelu ijo ati ayo.
- Aabo /idaji emu tabi Aabo/Ilaji igan isana ni won yoo fi ranse si idile iyawo ti oko ko b anile lati fi han pe aloku iyawo ni won gbe fun oun.
Anfani Ikora eni ni Ijanu - O n mu ki Oko nife Iyawo re denu.
- O n fun Obinrin ni iyi ati eye ni ile oko.
- O je ohun iwuri fun omobinrin ati iya re
- O n dena aisan kiko lati ibi ibalopo
- O n dena fifi omo ale se akobi.
Ewu Ailekora eni ni Ijanu - Oyun ojiji le waye
- Ile omobinrin le baje nibi isekuse
- Obinrin le ko aisan atosi ati jeerijeeri.
- Igbeyawo airotele le waye bi obinrin ba se asemase.
- Itiju ati abuku ni o n ko ba idile obinrin.