IRAN RA ENI LOWO NI ILE YORUBA

JSS 2 2nd week note 3rd term.
IRANRA ENI LOWO NI ILE YORUBA.
(1) AARO
Ise oko ti o ba po ni won maa n gba aaro si. Awon igiripa okunrin ti won le sise bakan naa ni won maa n se aaro. Itumo re ni ba mi ro temi, ki n ba o ro tire. Inu oko eni ti won ba lo se aaro ni won yoo ti jeun aaro ati to Osan.
Awon ti won n se aaro yii maa n po, won yoo lo sinu oko enikan lonii, elomiiran lola ti ti yoo fi fi kan gbogbo awon omo egbe. Aaro ni esan adapada.
(2) OWE)
Eyi ni ona ti won maa n gba ran eni ti o be owe lowo lati se awon ise akanse nla to apa iru eni bee ko ka.
Awon ise akanse bee to a le be owe fun ni:
(I) ile kiko
(ii) Ona oko yiye
(iii) odo gbigbe/Kiko
(iv) eru riru lati inu oko wa sinu aba.
Owe ko ni esan adapada.
(3) AJO
Ajo je Ona lati ko owo jo fun ojo ola. Awon eniyan pupo lo maa n da ajo, ipari osu ni won maa n ko ajo, ko pondandan ki gbogbo won o mo ara won tan.
Owo ti a ba koko da je ti alajo, ohun ni a n pe ni adadeyin.
(4) ARADOSU
Eyi n waye nigba ti a ba ra oja lowo oloja pelu adehun lati San owo oja naa fun oloja ni ipari osu.
(5) OWO ELE KIKO
Eyi ni sisan ilopo meji owo ti a ya lowo olowo, ohun naa ni won n pe ni “sogundogoji” .
(6) SANDIEDIE
Eyi n waye nigba ti a ba ra oja low nio oloja pelu adehun pe a o ma san owo oja naa diedie ti to a o fi san- an tan fun oloja.
Aafaani ona iranra eni lowo.
(I) o maa n mu ki ise ya
(ii) o maa n bo ni asiri
(iii) o maa n je ki a ni dukia ti o po.
(iv) o maa n wu ni Lori.
ALEEBU ONA lRANRA ENI LOWO
(I) o maa n mu ni da oko ti o po ju eyi ti agbara ka lo.
(ii) kii fi ni lokan bale
( iii) o le fa ija tabi ikunsinu.