ISARE AJEMESIN


Topic: lSARE AJEMESIN.
O hun pipe ti awon babanlawa nlo ni idi esin orisa kan ati eyi ti ko je mo esin to wa fun ayeye ni isare tumo si.
Apeere lsare Ajemesin. 1) ljala 2) Rara 3) Arungbe 4) Efe 5) lyere- lfa 6) lwi/Esa-Egungun 7) Esu pipe 8) Oya pipe 9) Sango pipe 10) lremoje.
IJALA: Awon olusin ogun, awon ode ni won maa n ko ara won jo lati dupe lowo ogun, lati fi imoriri han si yala lakoko ti won n se odun Ogun tabi lakoko ti won ba fe lo sinu igbo lo peran. Orin ti awon agba ode nko yii, ni won n pe ni IJALA sisun.
2) lWI/ESA EGUNGUN.
Awon eleegun lo ma n pe esa lati yin orisa egungun lakoko ti won ba n se ayeye odun egungun, tabi ti won ba bo orisa egungun.
3) ARUNGBE: Awon Oloro ni won maa nko orin Oro ti won pe ni Arungbe lakoko ti won ba n bo orisa Oro.( Egba lo ni i)
4) EFE: orisa Gelede lo ni ewi alohun EFE, Yewa lo ni i. Orin ti won n ko nigba ti won ba n bo orisa Gelede ni orin EFE je.