1 of 2

Itesiwaju Lori Ibanisoro

ITESIWAJU LORI ONA IBANISỌRỌ AYÉ – ATIJỌ

  1. Iparoko:
    Aroko jẹ ona kan ti a n gba ba ara eni sọrọ ni aye atijọ . Bi awọn agba ba fẹ sọrọ asiri ti eni ti won fẹ sọ ọ fún ko si nítòsí , tàbí tí wọn bá fẹ ranṣẹ silẹ ni asiri, àrokò ni wọn n lo . Àrokò pipa ranṣẹ si ni ko gba ṣiṣe alaye rẹpẹtẹ. Àrokò ni yóò túmọ ara rẹ fún ẹni tí a bá ran an si.
    Àpẹẹrẹ:
    (i) Ìlú lilu: Ní ilẹ Yorùbá, ilu n ko ipa pataki ninu ọnà ibanisọrọ ni ayé àtijọ. Orisiirisii ilu ni o wa bẹẹ sì ni gbogbo wọn ni a fi n sọrọ Ko si ohun ti wọn ko le fi ilu wí.
    (ii) Ẹdan Ògbóni: Ẹdan jẹ orísìí ọpa ti Ògbóni kan ti o maa n ni ère ni ori rẹ. Bi ẹnìkan ba je gbeṣe , ti wọn wa fi edan ran Ògbóni ránṣe sí i, ẹni náà ko gbọdọ jafara bi o ba ti ri i gbà. O ni lati wa owo náà san kiakia.
    (iii) Opa Àṣẹ: Oba nikan ni o n fi opa àṣẹ paroko. Nitori pe kii se gbogbo odẹ ni ọba lè é lo,opa àṣẹ yii ni ọba maa n gbe ranṣẹ láti fi han wipe oun wa níbẹ.
    (iv) Ìrukẹrẹ: Oba, Baalẹ , Ìjòyè ati Agba awo ni wọn fi Ìrukẹrẹ paroko. Ti wọn ba yọ eyọ irun irukẹrẹ kan, ki wọn ta ni kókó si inú aṣọ pupa, ti wọn ba fi ranṣẹ si ẹnikan, àpẹẹrẹ ija tabi wiwa pípọn oju ẹni tàbí pe ija n bọ ni yi.
    (v) Owo Ẹyo: Awọn babalawo ati oloriṣa-oko ni wọn fi ọwọ ẹyọ paroko. Elo miiran si le lo o. Ipe pajawiri lórí ki a fi oju kan nini eyi maa n túmọ si.
    (vi) Awọ Ẹdun: Ẹdun ni nkan an ṣe pẹlú oriṣa ibeji . Ti babalawo ba fi ranṣẹ si ọkunrin ti iyawo re wá nínú oyun, o túmọ si pe ibeji ni iyawo re yi o bi .
    (vii) Ṣìgìdì: Bi wọn ba gbe Ṣìgìdì sì ile ọkunrin kan pẹlu ila oju , ọkunrin naa ni ẹrẹkẹ ọtun un Ṣìgìdì ati ila obinrin kan ni ẹrẹkẹ o si Ṣìgìdì, a jẹ pé ọkùnrin náà ni ajọṣepọ ikọkọ pẹlu obinrin ti ila rẹ wa lójú Ṣìgìdì náà. Ki o tètè jawọ ni bẹ bi ko ba fẹ tẹ. Àròko ìkìlọ ni yi.
    (viii) Iyẹ Adìyẹ: Ti a ba tu iyẹ adiyẹ ṣẹhinkule ọkunrin kan, ìkìlọ ni yi pe , ki o jáwọ nínú nini ajọṣepọ pẹlu obinrin olobinrin.
    (ix) Ebiti ati Awọ Ehoro: Eyi túmọ si pe ibi ti eni ti a fi nnkan wọnyi ranṣẹ si léwu, ki o tètè kúrò ni bẹ.
    (x) Owo Ẹyọ mẹta: ti a ba dii ranṣẹ si eniyan, ẹni ti a paroko ranṣẹ sí náà ti ṣẹ̀ ati pe o ti di eni itanu fún ẹni ti o paroko náà ranṣẹ. Ìbáwí ni yí