1 of 2

Itesiwaju Lori ise abinibi

Ìtẹsiwaju Lórí Àtúnyẹwò Iṣẹ Abinibi
Oriṣii Àgbẹ tó wa;

 1. Àgbẹ Alarojẹ:- Irú àgbẹ yii maa ń da oko ti wọn lè fi bọ ebi woń. Àgbẹ alarojẹ maa ń gbin awon nnkan bii àgbàdo ege, ọgẹdẹ,ata ati ewebẹ loriṣiriṣi.
 2. Àgbẹ Alada-nla/ Ọlọkọ-Nla: Eyi ni awọn àgbẹ ti won ń fi iṣẹ àgbẹ ṣiṣe ṣe iṣẹ. Iru awọn àgbẹ yìí maa ń da oko nla, wọn sì maa ń kore púpọ.Iru awọn àgbẹ yìí máa ń gba awọn oṣiṣẹ lati na wọn ṣiṣẹ.
  Oriṣii Ilẹ ti Àgbẹ ń dá.
 3. Ilé igbo: Irú ilẹ yìí ni wọn máa ń gbin awọn igi owo bii kókó, obì,orogbo, ọpẹ, ọsán, rọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.
 4. Ilẹ ọ̀dan:- Ilẹ yìí dara lati gbin agbado, iṣu, ẹgẹ, ẹgusi,ẹwa,ọka-baba, òwú, ẹpa,anamo ati eso.
 5. Ilẹ Àkùrò:- Ilẹ Àkùrò dara fún ọgbin agbado, ìla, ata, ẹfọ,ireke ati eso loriṣiriṣi.
  Ohun-elo iṣẹ Àgbẹ
  Awọn ohun-èlo iṣẹ àgbẹ ni ọkọ,ada, aake, ìdòjé ati ọ̀bẹ
 6. IṢẸ ÀGBEDE:- Awọn alagbẹdẹ ni wọn máa ń fi irin rọ oríṣiríṣi awọn ohun-èlo bíi ọbẹ,àdá, ọkọ,dòjé ati bẹẹ bẹẹ lọ. Iṣẹ agbẹdẹ jọ iṣẹ Wẹ́dà ni aye ode-ònì. Itan sọ pẹ “Ogun Làádin” ni alagbẹdẹ akọkọ ni aafin Ile-Ifẹ.
  Iwulo iṣẹ Agbẹdẹ
 7. Awọn ni wọń rọ ọkọ, àdá,aake, ọbẹ fun awọn àgbẹ.
 8. Awọn ni wọn ń rọ irin fun ferese laye ofe-oni
 9. Awọn ni wọn maa ń jo ibi ti ó ba jẹ lara ọkọ ni aye ode oni.
  Ohun Elo wọn
  Ohun elo wọn ni owú, ọmọ-owú,pọnrin,ewiri,emú ati eesan. Awọn ajorin ode-oni ń lo ina gaàsi, kanbaadi,irin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
 10. OWO ṢIṢE
  Eyi ni a tún mọ si kara-kata. Iṣẹ owo pi n si oríṣi meji. Alajapa ni awọn ti wọn máa ń ra nnkan oko bii agbado,ata, ọgẹdẹ, iṣu, èlùbó,gaari, ọsán ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn miiran jẹ oniṣowo alada-nla ti wọn máa ń ta aṣọ òfì,bata ati awọn nnkan ti a fi ń ṣe ara ẹni lọṣọọ loriṣiriṣi.
  Pataki Ìwúlò iṣẹ oniṣowo
 11. Wọn máa ń jẹ ki oja de arọwọto awọn onraja lásìkò.
 12. O ń pese iṣẹ aṣela fun ontaja
  Ohun-elo ìṣòwò
 13. Owo Idokowo: Eyi ni owo ti a fi ń ra oja lati ta.
 14. Ibi iṣowo: Ibi ti a ti ń ta ọja.
 15. Ipolowo oja: Ipolowo oja ni agunmu owo. Awọn oniṣowo máa ń polowo ọja ní agunmu owo.
  Awọn oniṣowo máa ń polowo ọja wọn lati jẹ ki awọn eniyan mọ̀
  Ọnà Ikọṣẹ
  Omo le kọ iṣẹ owo ni ọna obì tabi kí o lọ kọ ọ ni ọdọ ẹni ti o ba ń ṣe irú owo bẹẹ.