Ogun ati Alaafia

       OGUN ATI ALAAFIA

OGUN ni ija laaarin awon eniyan kan ni ilu tabi Orile-ede tio fa lilo awon ologun ati nnkan ija ogun. O je akoko wahala ati idaamu, ti opolopo emi maa n sofo.
ALAAFIA ni wiwa ni ifokanbale, to ko si ogun, wahala, tabi ede ayede.
Awon ohun to n fa ogun
i. Aala ile ilu ti won ko fi suuru yanju.
ii. Fifi agidi je oye idile ti ko to si ni.
iii. Yiye adehun sisan isakole tabi Kiko asingba laarin ilu meji.
iv. Obinrin gbigba lona iwosi.
v. Aifagba fun eni ti agba to si laaarin ilu kekere ati ilu nla.
Ogun to ti waye ni ile Yoruba laye atijo
I. Ogun ijaye ati ibadan.
II. Ogun kiriji
III. Ogun owiwi
IV. Ogun Egba ati Ota
V. Ogun jalumi.
VI. Ogun Ife ati Modakeke
VII. Ogun Ijemo
VIII. Ogun Adubi ni Abeokuta.
Ohun Elo Ogun
i. Ijakadi,
I. oko siso lu ara won
II. Kannakanna
III. Ofa
IV. Kondo
V. Akatampo
VI. Ebo riru

Anfaani Ogun jija
I. O je ona idaabobo ilu wni lowo ota.
II. O je ki a mo bi ilu eni se lagbara ogun jija to.
III. O n mu ki ilu wa ni imurasile ni gbogbo igba
IV. O mu ni ko erú ati erù bii ikogun
V. O nje ki a mo awon ole ati alagbara ilu.
Aleebu Ogun jija
ii. Ogun maa n da ota sile laaarin ilu meji.
iii. Fifi emi ati dukia sofo.
iv. Ogun apoju maa n fa iyan
v. O maa n so opo eniyan di alaabo ara
vi. Ogun maa n je ki owo eru waye.
Ona lati dekun Ogun
I. Nini suuru lati yanju Oro
II. Nini ipamora
III. Ibowo fun omolakeji
IV. Nini ife ara wa denu
V. Nini iwa pele
VI. Yiyago fun aawo tabi ija ni gbogbo ona
VII. Nini emi idariji
ISE SISE:
i. So nnkan marun-un ti o le fa ogun.
ii. Menu ba orisi nnkan ija ogun marun-un ti o mo.
iii. Awon ona wo ni a le fi dekun ogun ni awujo wa. Menu ba meta.