1 of 2

Ona Ibanisoro

ỌNA IBANISỌRỌ
Ibanisọrọ ni ọna ti ènìyàn meji tàbí jù bẹẹ lọ ń gba fí èrò inú wọn hàn sí ara lọnà ti o fí yé wọn yékéyéké. Ọnà yìí ni a ń pé ni èdè. Èdè ni o n fún ohun tí a ń sọ ni ìtumọ̀. Bi ẹni méjì tí wọn kò gbọ èdè ara ba n sọrọ, bi ariwo lasan ní ohun tí wọn ń sọ.
ONA IBANISỌRỌ NI AYÉ ÀTIJỌ

  1. Lilo Ẹyà Ara fún Ibanisọrọ
    Ẹyà ara ti a ń lo fún Ibanisọrọ jẹ awọn ẹyà ara ti a le gbe soke sodo, ti eni ti a ń fi i ba sọrọ le rí. Ẹni bẹẹ le wa ni ẹgbẹ ẹni tabi wa níbí ti ko jìnnà. Àpẹẹrẹ àwọn ẹyà ara náà ni wọnyi:
    (i) Ojú: Oju ṣe pàtàkì nínú ẹyà ara ifọ Bi àpẹẹrẹ, a lè fi ojú fa ni mọra , kilọ fún ènìyàn bẹẹ ni a le fi na ènìyàn lailo pasan . Awọn Yorùbá ká ọmọ ti o ba mọ oju kún ọmọ ti o gbọn ti o si loye. Wọn a ni “O mọ ojú o mọ ara “.
    (ii) Ori: Ipa pataki ni ori n kọ bii ọnà ibanisọrọ . Igba miiran , ènìyàn le so ori kọ , won a ni oluwa rẹ ń ronú . Bi o ba n fi ọwọ ja orí , to n fi ẹsẹ jalẹ , àjálù laabi kan ni o ṣẹlẹ sí i.
    (iii) Imú: Yorùbá kii i dédé yín imú ti kò bá sì ija tabi ikunsinu.
    (iv) Ẹnu: A lè lò ẹnu lai ya a tàbí si i rárá.
    (v) Ejika:
    Bi a ba n bá ní i sọrọ tí a gbun tàbí sọ ejika

Mo gba ọrọ naa5 wọlé bìí òtítọ́
Mo lòdì sí ọrọ náà.

(vi) Ẹṣẹ:
Bi a ba fi ẹṣẹ janlẹ Àmì ilodi si nnkan kan ni eyi jẹ
Tite eniyan lẹṣẹ mọlẹ À ń kilọ fún pe ki o ma ṣe nnkan kan tabi ki o dakẹ.
À le fi pé akiyesi rẹ sí nnkan kan.

(vii) Eekanna:
Ṣíṣe ni leekanna : Ìkìlọ ni pe ki o dakẹ ọrọ tàbí fi pe àkíyèsí rẹ sí nnkan kan.
(viii) Ọwọ: Ilo ọwọ bi ona ibaniọrọ pọ . A le ju ọwọ si ènìyàn pe kí o wa , bẹẹ ni a le ya ọwọ kan
naa yii láti bu ni
(ix) Ète: Orisiirisii ọna ni a le gba lo ète lati sọrọ.
Àpẹẹrẹ:
A le yọ suti ète: Lati fi saata tabi bu ni
A le yọ ete si enikan: lati júwe tàbí sọ ibi ti nnkan wa.