ITESIWAJU LORI ONKA EDE YORUBA*
Onka ni eko nipa isiro sise lati fi ka iye nnkan ti a ni tabi lati fi mo ipo ti eniyan ati nnkan ti jeyo.
Ninu iwe kinni ati ko nipa;
-Lilo ami aropo (+) “le”
-Lilo ami iyokuro(-) “din”
-Lilo “aado” gege bi ipile bere lati aadota(50)
-Lilo “okoo”, oji, ota, orin, gege bi ipile bere lati igba(200)
-Lilo “eede” gege bi ipile bere lati eedegbeta(500) fun awon nomba nlanla ti igba (200) ko le pin geere. Eede tumo si iyokuro Ogorun/orun(-100) ninu isodipupo igba( multiplication of 200)
Apeere:
820=800+20=okoo-le-le-gberin
840=800+40=oji-le-le-gberin
860=800+60=ota-le-le-gberin
880=800+80=orin-le-le-gberin.
1000=200×5=(igba marun-un) =Egberun.
Onka lati Egberun kan de Egberun meji (Egbaa)
1000 Egberun (igba marun-un) 200×5
1100 Eedegbefa (orun- din-ni-egbefa) 200×6-100
1200 Egbefa (igba mefa) 200×6
1300 Eedegbeje(orun din ni egbeje) 200×7-100
1400 Egbeje (igba meje) 200×7
1500 Eedegbejo. (Orun din ni egbejo) 200×8-100
1600 Egbejo. (Igba mejo) 200×8
1700 Eedegbesan-an (orun din ni egbesan-an) 200×9-100
1800 Egbesan/-an. (Igba mesan-an ) 200×9
1900 Eedegbewa (orun din ni egbawa) 200×10+100
2000 Egbewa/Egbaa. ( Igba mewa) 200×10