ORISI GBOLOHUN

          
   

 ORISI GBOLOHUN

Gbolohun ni iso ti o ni itumo kikun.
GBOLOHUN ALABODE( Simple sentence)
Eyi no gbolohun kukuru, ti ko ni ju eyo oro-ise Kan lo. Apeere:
Olu lo si oja
Ranti sun
Won mu osan
Omo yii rewa
Ade subu yakata.
GBOLOHUN ALAKANPO( Compound sentence)
Gbolohun alakanpo ni inu gbolohun ti a ti maa n lo oro asopo kan lati so gbolohun eleyo Oro ise meji po.
Apeere:
Bola ati Ayo lo si ile-iwe
Olu wa sugbon ko jeun
Bimpe lo tabi ko lo?
Gbolohun Alakanpo maa n ni ju oro- ise kan lo.
Apeere:

Olu lo si oja sugbon ko ri ata ra.
Kunle ga o si tere.
Mo fi abo jeun amo ko fo o.
GBOLOHUN ONIBO( Complex sentence)
Gbolohun onibo ni inu gbolohun ti a ti fi gbolohun kan bo inu gbolohun miiran.
Awe meji ni gbolohun onibo maa n ni, awon ni:
Olori awe gbolohun ati Awe gbolohun afarahe tabi afibo. Apeere:
Aso ti won ra dara
O dara pe n ko soro
Bimpe da bata ti mo ra nu.
Awe gbolohun afibo ni a fala si nidii ninu awon apeere oke wonyii.
IDANRAWO
Iru isori gbolohun wo niwonyi:
i. Olu ati Ayo wo orisi aso kan naa.
ii. Mo feran iya mi.
iii. Bata ti mo wo funfun.
iv. Olu ti lo ki n to de.
v. Tunde je isu yo.