Owo sise

             OWO SISE 1

Owo sise tabi karakata je okan ni Ara ise aje Yoruba. Erongba ontaja ni lati jere, nitori “ ere ni omo oloja n je”. Eni ti o ta oja ti ko jere ni won ni o sowo sooti.
PATAKI OWO SISE NI ILE YORUBA
i. O maa n je ki a ni ise lowo
ii. O n le osi danu, a si so eniyan di olow.
iii. O n mu ni I tepa mose, ki a ma sole
iv. O n mu ki ire oko wolu lopo yanturu.
v. O maa n sokunfa ajosepo laaarin eya Yoruba ati eya miiran.
vi. O n mu ni gbajumo.
vii. O n mu ki oja okeere wa ni arowoto ara ilu.
ORISII OWO TI YORUBA N SE
i. Arobo/Agbata
Awon alarobo ni won n lo ra oja lowo oloko ti won wa n tun un ta fun alajapa. Awon naa yoo fi owo die le.
ii. Alajapa
Awon ni won ra oja lowo alarobo tabi alagbata. Awon ni won n tun oja ta fun awon ara ilu.
iii. Ounje Tita (Sise tabi tutu)
Owo ounje tita ni tutu tabi sise je okan pataki ninu owo sise ni ile Yoruba. Awon olounje bee le pate oja won si oju kan tabi ki won maa kiri yika adugbo. Apeere ounje bee ni:
Iresi, Amala, Isu, Agbado,Iyan,Akara.
iv. Worobo/wosiwosi
Oniworobo ni awon to n ta awon nnkan peepeepe. Iwonba owo perete ni won fi n bere oja. Won le pate oja won si oju kan tabi ki wonaa kiri. Apeere oja ti won n ta ni:
Atike, Ose-iwe, Bisiki, eyin, orin pako, ipara
v. Eran Osin
Ojukan ni awon onisowo eren osin maa n ko eran ti won n ta si ti onibaara yoo si maa wa ra nibe. Awon eran osin bee ni:
Ewure, maluu, adie, Agutan, pepeye, elede, eja odo.