1 of 2

Ibanisoro ode oni

IBANISỌRỌ AYE ODE ÒNÍ
Ni òde òní, ede ni òpómúléró ọnà ibanisọrọ. Ede ni a fi n ṣe àmúlò agbara láti ronú ti a o sì sọ èrò inú wa jáde fún agbọye; ti a fi n ṣàlàyé ohunkohun. Ohun ni a fi n ba ni kẹdun, ti a fi n ba ni yo, ohun ni a fi n kọ ni lekọọ ni ile ati ni ile ìwé. Ede ni a fi n gbani ni iyànjú, ti a tún fi n danilaraya. Pataki ede ni awujọ ko kéré.
Bi ko ba si èdè, redio , iwe iroyin ko lè wúlò. Ede ni redio àti telifisan fi n danilaraya, ti wọn fi n fi kọ ní lekọọ, ti wọn fi n royin. Olaju esin ati ti ẹkọ imọ sayẹnsi ti mu aye lu jara nipa imọ ẹrọ. Awọn ona ibanisọrọ ode oni ni wọnyi:
(i) Ìwé Ìròyìn: Ipa pataki ni iwe ìròyìn n ko bii ona ibanisọrọ. Henry Townsend ni o kọkọ tẹ “Iwe Ìròyìn fún àwọn Ègbá ati Yorùbá” jáde ni ede Yorùbá ni ọdún 1859. Gẹgẹ bíi ọnà ibanisọrọ , wọn n kọ ní lekọọ, danilaraya, bẹẹ ni wọn n lani lóyè.
(ii) Telifisọn: Ilẹ Yorùbá náà ni Telifisọn akọkọ ni ilẹ eniyan dúdú ti bẹrẹ ni ilu Ibadan. Bi orukọ rẹ “Ero- Amohun- Maworan” ni a n pè é. Anfaani gbigbọ ọrọ ati rírí aworan awọn eniyan inu rẹ wo je ìrànlowo ti ko ni àfiwé ninu gbigbe ede ati aṣa Yorùbá larugẹ . Ona kaan naa niyi ti a fi gbé èrò ẹni si ori eto, ti ibanisọrọ si n wáyé.
(iii) Redio:Ojo redio naa ti pe ni ile Yoruba. Bii orukọ rẹ “erọ-asoromagbesi” oro lásán ni a n ti wọn n sọ ni ori eto okan-o-jokan wọn . Anfaani wa fún ènìyàn lati gbe èrò wọn si ori afẹfẹ láti fi danilaraya, ko ni lekọọ, ni lekọọ ati laniloye.
(iv) Pako Alarimọle lébàá Títí àti Iná Adari-Oko: Awọn pátákó alarimole wa káàkiri oju popo ti wọn n juwe tàbí dari ẹni si òpópó-ònà laarin ilu nla nla . Bẹẹ ni ina adari-oko wa ni ojúú Pop ti won n dari ọkọ. Awo mẹta ni awọn fi n paroko lilọ ati diduro ọkọ ni ikorita . Awo pupa dúró fun ‘duro’, ewu wa lọnà: awọ olómi ọsán ni ki a si ina oko ni imura silẹ lati lọ , bẹẹ ni awo ewe ni ki ọkọ máa lọ.
(v) Ẹrọ-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti) Ẹrọ ayelujara jẹ gbàgede agbaye to si silẹ fún teru-tọmọ, ti a le lo, to si wa ni àrówòtó gbogbo eniyan. Ero ayelujara ati awọn ero ilaniloye miiran ati awọn imọ ero ibanisọrọ (ICT); jẹ ohùn èlò alagbara fún itaniji aráàlú ati idagbasoke àti ìlọsíwájú ibanisọrọ (APC) . Èrò yìí ko ipa ribiribi ni ṣiṣe kokaari ilaniloye ati ibanisọrọ , láìsí idiwọ tani ìnira. Ko sí imọ ti a n fẹ lórí èdè, ọna ibanisọrọ ti ẹrọ ayelujara ko ni ṣàlàyé re fun ni.
(vi) Lẹta Kiko: Leta kikọ jo àròkọ ayé àtijọ ni orisirisi ona . Gbigbe ni an gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe àròkọ ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo iwe lẹta, titu náà ní a n tu gbinrin ti a di, kika la n ka lẹta , wiwo ni an ami àròkọ. A le kọ ohùn ti a ni lọkàn si inu lẹta, fi ranṣẹ si ẹni ti a ko si ninu àpo ìwé. Igba ti wọn ba tu ni wọn yi o to mọ ohun to wa ní bẹ.
(vii) Foonu: Oro náà ni a n sọ si inú foonu ti ẹni ti o wa ni odi keji ti a n pe n gbọ. Bi oun náà ba fe si awa ti a n pe náà yóò gbọ. Ona ibanisọrọ yi i ti di ilumoka ni ile Yoruba. A le wa ni Eko, ki a ma takuroso pẹlu eni ti o wa ni Ilu Oyinbo!
(viii) Agogo: Bi o tile jẹ pe agogo jẹ ohùn èlò iparoko aye àtijọ, won si n lo won bi ona ibanisọrọ ode oni. Bi àpẹẹrẹ:
a. Agogo ile isin lílu – lati pe eniyan lati wa jọsin ni ṣooṣi.
b. Agogo ọmọ ile iwe – lati fi pe awọn akẹkọ wọlé.
c. Agogo onisowo – lati fi fà onibara won mọra.